Num 8 YCE

Ìgbékalẹ̀ Fìtílà

1 OLUWA si sọ fun Mose pẹ,

2 Sọ fun Aaroni, ki o si wi fun u pe, Nigbati iwọ ba tàn fitila, ki fitila mejeje na ki o ma tàn imọlẹ lori ọpá-fitila.

3 Aaroni si ṣe bẹ̃; o tàn fitila wọnni lori ọpá-fitila na, bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.

4 Iṣẹ ọpá-fitila na yi si jẹ̀ ti wurà lilù; titi dé isalẹ rẹ̀, titi dé itanna rẹ̀, o jẹ́ iṣẹ lulù: gẹgẹ bi apẹrẹ ti OLUWA fihàn Mose, bẹ̃li o ṣe ọpá-fitila na.

Ìwẹ̀nùmọ́ ati Ìyàsímímọ́ Àwọn Ọmọ Lefi

5 OLUWA si sọ fun Mose pe,

6 Yọ awọn ọmọ Lefi kuro ninu awọn ọmọ Israeli, ki o si wẹ̀ wọn mọ́.

7 Bayi ni ki iwọ ki o si ṣe si wọn, lati wẹ̀ wọn mọ́; Wọn omi etutu si wọn lara, ki nwọn ki o si fá gbogbo ara wọn, ki nwọn ki o si fọ̀ aṣọ wọn, ki nwọn ki o si wẹ̀ ara wọn mọ́.

8 Ki nwọn ki o si mú ẹgbọrọ akọmalu kan pẹlu ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ani iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, ati ẹgbọrọ akọmalu keji ni ki iwọ ki o mú fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ.

9 Ki iwọ ki o si mú awọn ọmọ Lefi wá siwaju agọ́ ajọ: ki iwọ ki o si pe gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli jọ pọ̀:

10 Ki iwọ ki o si mú awọn ọmọ Lefi wá siwaju OLUWA: ki awọn ọmọ Israeli ki o si fi ọwọ́ wọn lé awọn ọmọ Lefi.

11 Ki Aaroni ki o si mú awọn ọmọ Lefi wá siwaju OLUWA, bi ọrẹ fifì lati ọdọ awọn ọmọ Israeli wá, ki nwọn ki o le ma ṣe iṣẹ-ìsin OLUWA.

12 Ki awọn ọmọ Lefi ki o si fi ọwọ́ wọn lé ori ẹgbọrọ akọmalu wọnni: ki iwọ ki o si ru ọkan li ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ekeji li ẹbọ sisun si OLUWA, lati ṣètutu fun awọn ọmọ Lefi.

13 Ki iwọ ki o si mu awọn ọmọ Lefi duro niwaju Aaroni, ati niwaju awọn ọmọ rẹ̀, ki o si mú wọn wá li ọrẹ fifì fun OLUWA.

14 Bẹ̃ni ki iwọ ki o yà awọn ọmọ Lefi sọ̀tọ kuro lãrin awọn ọmọ Israeli: awọn ọmọ Lefi yio si jẹ́ ti emi.

15 Lẹhin eyinì li awọn ọmọ Lefi yio ma wọ̀ inu ile lọ lati ṣe iṣẹ-ìsin agọ́ ajọ: ki iwọ ki o si wẹ̀ wọn mọ́, ki o si mú wọn wá li ọrẹ fifì.

16 Nitoripe patapata li a fi wọn fun mi ninu awọn ọmọ Israeli; ni ipò gbogbo awọn ti o ṣí inu, ani gbogbo akọ́bi ninu awọn ọmọ Israeli, ni mo gbà wọn fun ara mi.

17 Nitoripe ti emi ni gbogbo akọ́bi ninu awọn ọmọ Israeli, ati ti enia ati ti ẹran: li ọjọ́ ti mo kọlù gbogbo akọ̀bi ni ilẹ Egipti ni mo ti yà wọn simimọ́ fun ara mi.

18 Emi si ti gbà awọn ọmọ Lefi dipò gbogbo akọ́bi ninu awọn ọmọ Israeli.

19 Emi si fi awọn ọmọ Lefi fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀ li ọrẹ lati inu awọn ọmọ Israeli wá, lati ma ṣe iṣẹ-ìsin awọn ọmọ Israeli ninu agọ́ ajọ, ati lati ma ṣètutu fun awọn ọmọ Israeli: ki àrun má ba sí ninu awọn ọmọ Israeli, nigbati awọn ọmọ Israeli ba sunmọ ibi-mimọ́.

20 Bayi ni Mose, ati Aaroni, ati gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, ṣe si awọn ọmọ Lefi: gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA paṣẹ fun Mose niti awọn ọmọ Lefi, bẹ̃li awọn ọmọ Israeli ṣe si wọn.

21 Awọn ọmọ Lefi si wẹ̀ ara wọn mọ́ kuro ninu ẹ̀ṣẹ, nwọn si fọ̀ aṣọ wọn; Aaroni si mú wọn wá li ọrẹ fifì siwaju OLUWA: Aaroni si ṣètutu fun wọn lati wẹ̀ wọn mọ́.

22 Lẹhin eyinì ni awọn ọmọ Lefi si wọle lọ lati ṣe iṣẹ-ìsin ninu agọ́ ajọ niwaju Aaroni, ati niwaju awọn ọmọ rẹ̀: bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose niti awọn ọmọ Lefi, bẹ̃ni nwọn ṣe si wọn.

23 OLUWA si sọ fun Mose pe,

24 Eyi ni ti awọn ọmọ Lefi: lati ẹni ọdún mẹdọgbọ̀n lọ ati jù bẹ̃ lọ ni ki nwọn ki o ma wọle lọ lati ṣe iṣẹ-ìsin ninu agọ́ ajọ.

25 Ati lati ẹni ãdọta ọdún ni ki nwọn ki o ṣiwọ iṣẹ-ìsin, ki nwọn ki o má si ṣe sìn mọ́;

26 Bikoṣepe ki nwọn ki o ma ṣe iranṣẹ pẹlu awọn arakunrin wọn ninu agọ́ ajọ, lati ma ṣe itọju, ki nwọn ki o má si ṣe iṣẹ-ìsin mọ́. Bayi ni ki iwọ ki o ṣe si awọn ọmọ Lefi niti itọju wọn.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28 29 30 31 32 33 34 35 36