1 OLUWA si sọ fun Mose pe,
2 Fi aṣẹ fun awọn ọmọ Israeli pe, ki nwọn ki o mú oróro daradara ti olifi gigún fun ọ wá, fun imọlẹ lati ma mu fitila jó nigbagbogbo.
3 Lẹhin ode aṣọ-ikele ẹrí, ninu agọ́ ajọ, ni ki Aaroni ki o tọju rẹ̀ lati aṣalẹ di owurọ̀ nigbagbogbo niwaju OLUWA: ìlana ni titilai ni iran-iran nyin.
4 Ki o si tọju fitila lori ọpá-fitila mimọ́ nì nigbagbogbo niwaju OLUWA.
5 Ki iwọ ki o si mú iyẹfun daradara, ki o si yan ìṣu-àkara mejila ninu rẹ̀: idamẹwa meji òṣuwọn ni ki o wà ninu ìṣu-àkara kan.
6 Ki iwọ ki o si tò wọn li ẹsẹ meji, mẹfa li ẹsẹ kan, lori tabili mimọ́ niwaju OLUWA.
7 Ki iwọ ki o si fi turari daradara sori ẹsẹ̀ kọkan ki o le wà lori ìṣu-àkara na fun iranti, ani ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA.
8 Li ọjọjọ́ isimi ni ki ẹ ma tun u tò niwaju OLUWA titi; gbigbà ni lọwọ awọn ọmọ Israeli nipa majẹmu titi aiye.
9 Ki o si ma jẹ́ ti Aaroni ati ti awọn ọmọ rẹ; ki nwọn ki o si ma jẹ ẹ ni ibi mimọ́ kan: nitoripe mimọ́ julọ ni fun u ninu ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe, ìlana titilai.
10 Ati ọmọkunrin obinrin Israeli kan, ti baba rẹ̀ ṣe ara Egipti, o jade lọ ninu awọn ọmọ Israeli: ọmọkunrin obinrin Israeli yi ati ọkunrin Israeli kan si jà ni ibudó.
11 Eyi ọmọkunrin obinrin Israeli yi, sọ̀rọ buburu si Orukọ nì, o si fi bú: nwọn si mú u tọ̀ Mose wá. Orukọ iya rẹ̀ ama jẹ Ṣelomiti, ọmọbinrin Dibri, ti ẹ̀ya Dani.
12 Nwọn si ha a mọ́ ile-ìde, titi a o fi fi inu OLUWA hàn fun wọn.
13 OLUWA si sọ fun Mose pe,
14 Mú ẹniti o ṣe ifibu nì wá sẹhin ibudó; ki gbogbo awọn ti o si gbọ́ ọ ki o fi ọwọ́ wọn lé ori rẹ̀, ki gbogbo ijọ enia ki o le sọ ọ li okuta.
15 Ki iwọ ki o si sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹnikẹni ti o ba fi Ọlọrun rẹ̀ bú yio rù ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
16 Ati ẹniti o sọ̀rọ buburu si orukọ OLUWA nì, pipa ni ki a pa a: gbogbo ijọ enia ni ki o sọ ọ li okuta pa nitõtọ: ati alejò, ati ibilẹ, nigbati o ba sọ̀rọbuburu si orukọ OLUWA, pipa li a o pa a.
17 Ati ẹniti o ba gbà ẹmi enia, pipa li a o pa a:
18 Ẹniti o ba si lù ẹran kan pa, ki o san a pada: ẹmi fun ẹmi.
19 Bi ẹnikan ba si ṣe abùku kan si ara ẹnikeji rẹ̀; bi o ti ṣe, bẹ̃ni ki a ṣe si i;
20 Ẹ̀ya fun ẹ̀ya, oju fun oju, ehin fun ehin; bi on ti ṣe abùku si ara enia, bẹ̃ni ki a ṣe si i.
21 Ẹniti o ba si lù ẹran pa, ki o san a pada: ẹniti o ba si lù enia pa, a o pa a.
22 Irú ofin kan li ẹnyin o ní, gẹgẹ bi fun alejò bẹ̃ni fun ibilẹ: nitoripe Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.
23 Mose si sọ fun awọn ọmọ Israeli, pe ki nwọn ki o mú ẹniti o ṣe ifibu nì jade lọ sẹhin ibudó, ki nwọn ki o si sọ ọ li okuta pa. Awọn ọmọ Israeli si ṣe bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.