36 Ṣugbọn orisun tabi kanga kan, ninu eyiti omi pupọ̀ gbé wà, yio jẹ́ mimọ́: ṣugbọn eyiti o ba kàn okú wọn yio jẹ́ alaimọ́.
37 Bi ninu okú wọn ba bọ́ sara irugbìn kan ti iṣe gbigbìn, yio jẹ́ mimọ́.
38 Ṣugbọn bi a ba dà omi sara irugbìn na, ti ninu okú wọn ba si bọ́ sinu rẹ̀, yio si jẹ́ alaimọ́ fun nyin.
39 Ati bi ẹran kan, ninu eyiti ẹnyin ba ma jẹ, ba kú; ẹniti o ba farakàn okú rẹ̀ yio jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
40 Ẹniti o ba si jẹ ninu okú rẹ̀, ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ: ẹniti o ba si rù okú rẹ̀ ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
41 Ati ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ yio jasi irira; a ki yio jẹ ẹ.
42 Ohunkohun ti nfi inu wọ́, ati ohunkohun ti nfi mẹrẹrin rìn, ati ohunkohun ti o ba ní ẹsẹ̀ pupọ̀, ani ohun gbogbo ti nrakò lori ilẹ, awọn li ẹnyin kò gbọdọ jẹ; nitoripe irira ni nwọn.