32 Ni ijọ́ keje ki alufa ki o si wò àrun na: si kiyesi i, bi pipa na kò ba ràn, ti kò si sí irun pupa ninu rẹ̀, ti pipa na kò si jìn jù awọ ara lọ li oju,
33 Ki o fári, ṣugbọn ki o máṣe fá ibi pipa na; ki alufa ki o si sé ẹni pipa nì mọ́ ni ijọ́ meje si i:
34 Ni ijọ́ keje ki alufa ki o si wò pipa na; si kiyesi i bi pipa na kò ba ràn si awọ ara, ti kò ba jìn jù awọ ara lọ li oju; nigbana ni ki alufa ki o pè e ni mimọ́: ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si jẹ́ mimọ́.
35 Ṣugbọn bi pipa na ba ràn siwaju li awọ ara rẹ̀ lẹhin ìpenimimọ́ rẹ̀;
36 Nigbana ni ki alufa ki o wò o: si kiyesi i, bi pipa na ba ràn siwaju li awọ ara, ki alufa ki o máṣe wá irun pupa mọ́; alaimọ́ ni.
37 Ṣugbọn li oju rẹ̀ bi pipa na ba duro, ti irun dudu si hù ninu rẹ̀; pipa na jiná, mimọ́ li on: ki alufa ki o pè e ni mimọ́.
38 Bi ọkunrin kan tabi obinrin kan ba ní àmi didán li awọ ara wọn, ani àmi funfun didán;