39 Nigbana ni ki alufa ki o wò o: si kiyesi i, bi àmi didán li awọ ara wọn ba ṣe bi ẹni ṣe funfun ṣe dudu; ifinra li o sọ jade li ara; mimọ́ li on.
40 Ati ọkunrin ti irun rẹ̀ ba re kuro li ori rẹ̀, apari ni; ṣugbọn mimọ́ li on.
41 Ẹniti irun rẹ̀ ba re silẹ ni ìha iwaju rẹ̀, o pari ni iwaju; ṣugbọn mimọ́ li on.
42 Bi õju funfun-pupa rusurusu ba mbẹ li ori pipa na, tabi iwaju ori pipa na; ẹ̀tẹ li o sọ jade ninu pipa ori na, tabi ni pipá iwaju na.
43 Nigbana ni ki alufa ki o wò o: si kiyesi i, bi iwú õju na ba funfun-pupa rusurusu ni pipa ori rẹ̀, tabi pipa iwaju rẹ̀, bi ẹ̀tẹ ti ihàn li awọ ara;
44 Ẹlẹtẹ ni, alaimọ́ ni: ki alufa ki o pè e li aimọ́ patapata; àrun rẹ̀ mbẹ li ori rẹ̀.
45 Ati adẹ́tẹ na, li ara ẹniti àrun na gbé wà, ki o fà aṣọ rẹ̀ ya, ki o si fi ori rẹ̀ silẹ ni ìhoho, ki o si fi ìbo bò ète rẹ̀ òke, ki o si ma kepe, Alaimọ́, alaimọ́.