45 Ki o si wó ile na, okuta rẹ̀, ati ìti igi rẹ̀, ati gbogbo erupẹ ile na; ki o si kó wọn jade kuro ninu ilu na lọ si ibi aimọ́ kan.
46 Ẹniti o ba si wọ̀ ile na ni gbogbo ìgba na ti a sé e mọ́, ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
47 Ẹniti o ba dubulẹ ninu ile na ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀: ẹniti o jẹun ninu ile na ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀.
48 Ati bi alufa ba wọ̀ ile, ti o si wò o, si kiyesi i, ti àrun inu ile na kò ba ràn si i, lẹhin igbati a rẹ́ ile na tán; nigbana ni ki alufa ki o pè ile na ni mimọ́, nitoripe àrun na ti jiná.
49 Ki o si mú ẹiyẹ meji, ati igi opepe, ati ododó, ati ewe-hissopu wá, lati wẹ̀ ile na mọ́:
50 Ki o si pa ọkan ninu ẹiyẹ na, ninu ohunèlo amọ loju omi ti nṣàn:
51 Ki o si mú igi opepe, ati ewe-hissopu, ati ododó, ati ẹiyẹ alãye nì, ki o si tẹ̀ wọn bọ̀ inu ẹ̀jẹ ẹiyẹ ti a pa nì, ati ninu omi ṣiṣàn nì, ki o si fi wọ́n ile na nigba meje: