28 Ati ẹniti o sun wọn ni ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, lẹhin eyinì ni ki o wá si ibudó.
29 Eyi ni ki o si ma ṣe ìlana lailai fun nyin: pe li oṣù keje, li ọjọ́ kẹwa oṣù, ni ki ẹnyin ki o pọ́n ọkàn nyin loju, ki ẹnyin má si ṣe iṣẹ kan rára, iba ṣe ibilẹ, tabi alejò ti nṣe atipo lãrin nyin:
30 Nitoripe li ọjọ́ na li a o ṣètutu fun nyin, lati wẹ̀ nyin mọ́; ki ẹnyin ki o le mọ́ kuro ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ nyin niwaju OLUWA.
31 On o jẹ́ ọjọ́ isimi fun nyin, ki ẹnyin ki o si pọ́n ọkàn nyin loju, nipa ìlana titilai.
32 Ati alufa na, ẹniti a o ta oróro si li ori, ati ẹniti a o yàsimimọ́ si iṣẹ-alufa dipò baba rẹ̀, on ni ki o ṣètutu na, ki o si mú aṣọ ọ̀gbọ wọnni wọ̀, ani aṣọ mimọ́ wọnni:
33 Ki o si ṣètutu si ibi mimọ́, ki o si ṣètutu si agọ́ ajọ, ati si pẹpẹ; ki o si ṣètutu fun awọn alufa, ati fun gbogbo ijọ enia.
34 Ki eyi ki o si jẹ́ ìlana titilai fun nyin, lati ṣètutu fun awọn ọmọ Israeli nitori ẹ̀ṣẹ wọn gbogbo lẹ̃kan li ọdún. O si ṣe bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.