4 Ki o si mú ẹ̀wu ọ̀gbọ mimọ́ wọ̀, ki o si bọ̀ ṣòkoto ọ̀gbọ nì si ara rẹ̀, ki a si fi amure ọ̀gbọ kan dì i, fila ọ̀gbọ ni ki a fi ṣe e li ọṣọ́: aṣọ mimọ́ ni wọnyi; nitorina ni o ṣe wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si mú wọn wọ̀.
5 Ki o si gbà ọmọ ewurẹ meji akọ fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati àgbo kan fun ẹbọ sisun, lọwọ ijọ awọn ọmọ Israeli.
6 Ki Aaroni ki o si fi akọmalu ru ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ti iṣe ti on tikara rẹ̀, ki o si ṣètutu fun ara rẹ̀, ati fun ile rẹ̀.
7 Ki o si mú ewurẹ meji nì, ki o si mú wọn wá siwaju OLUWA si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ.
8 Ki Aaroni ki o si di ìbo ewurẹ meji na; ìbo kan fun OLUWA, ati ìbo keji fun Asaseli (ewurẹ idasilẹlọ).
9 Ki Aaroni ki o si mú ewurẹ ti ìbo OLUWA mú wá, ki o si fi ru ẹbọ ẹ̀ṣẹ.
10 Ṣugbọn ewurẹ ti ìbo mú fun Asaseli on ni ki o múwa lãye siwaju OLUWA, lati fi i ṣètutu, ati ki o si jọwọ rẹ̀ lọwọ lọ si ijù fun Asaseli.