9 Ki Aaroni ki o si mú ewurẹ ti ìbo OLUWA mú wá, ki o si fi ru ẹbọ ẹ̀ṣẹ.
10 Ṣugbọn ewurẹ ti ìbo mú fun Asaseli on ni ki o múwa lãye siwaju OLUWA, lati fi i ṣètutu, ati ki o si jọwọ rẹ̀ lọwọ lọ si ijù fun Asaseli.
11 Ki Aaroni ki o si mú akọmalu ẹbọ ẹ̀ṣẹ wá, ti iṣe ti on tikararẹ̀, ki o si ṣètutu fun ara rẹ̀, ati fun ile rẹ̀, ki o si pa akọmalu ẹbọ ẹ̀ṣẹ ti iṣe fun ara rẹ̀:
12 Ki o si mú awo-turari ti o kún fun ẹyin iná lati ori pẹpẹ wá lati iwaju OLUWA, ki ọwọ́ rẹ̀ ki o si kún fun turari didùn ti a gún kunná, ki o si mú u wá sinu aṣọ-ikele:
13 Ki o si fi turari na sinu iná niwaju OLUWA, ki ẽfin turari ki o le bò itẹ́-ãnu ti mbẹ lori ẹri, ki on ki o má ba kú.
14 Ki o si mú ninu ẹ̀jẹ akọmalu na, ki o si fi ika rẹ̀ wọn ọ sori itẹ́-ãnu ni ìha ìla-õrùn; ati niwaju itẹ́-ãnu ni ki o fi ìka rẹ̀ wọ́n ninu ẹ̀jẹ na nigba meje.
15 Nigbana ni ki o pa ewurẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, eyiti iṣe ti awọn enia, ki o si mú ẹ̀jẹ rẹ̀ wá sinu aṣọ-ikele, ki o si fi ẹ̀jẹ na ṣe bi o ti fi ẹ̀jẹ akọmalu ṣe, ki o si fi wọ́n ori itẹ̀-ãnu, ati niwaju itẹ́-ãnu: