1 OLUWA si sọ fun Mose pe,
2 Sọ fun gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Ki ẹnyin ki o jẹ́ mimọ́: nitoripe Emi OLUWA Ọlọrun nyin jẹ́ mimọ́.
3 Ki olukuluku nyin ki o bẹ̀ru iya rẹ̀, ati baba rẹ̀, ki o si ma pa ọjọ́ isimi mi mọ́: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.
4 Ẹ máṣe yipada si ere, bẹ̃ni ki ẹnyin má si ṣe ṣe oriṣa didà fun ara nyin: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.
5 Bi ẹnyin ba si ru ẹbọ alafia si OLUWA, ki ẹnyin ki o ru u ki ẹ le di ẹni itẹwọgbà.
6 Li ọjọ́ ti ẹnyin ru ẹbọ na ni ki a jẹ ẹ, ati ni ijọ́ keji: bi ohun kan ba si kù ninu rẹ̀ titi di ijọ́ kẹta, ninu iná ni ki a sun u.
7 Bi a ba si jẹ ninu rẹ̀ rára ni ijọ́ kẹta, irira ni; ki yio dà: