11 Ẹnyin kò gbọdọ jale, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ ṣe alaiṣõtọ, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ ṣeké fun ara nyin.
12 Ẹnyin kò si gbọdọ fi orukọ mi bura eké, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ bà orukọ Ọlọrun rẹ jẹ́: Emi li OLUWA.
13 Iwọ kò gbọdọ rẹ́ ẹnikeji rẹ jẹ, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ jẹ haramu: owo ọ̀ya alagbaṣe kò gbọdọ sùn ọdọ rẹ titi di owurọ̀.
14 Iwọ kò gbọdọ bú aditi, tabi ki o fi ohun idugbolu siwaju afọju, ṣugbọn ki iwọ ki o bẹ̀ru Ọlọrun rẹ: Emi li OLUWA.
15 Ẹnyin kò gbọdọ ṣe aiṣododo ni idajọ: iwọ kò gbọdọ gbè talaka, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ṣe ojusaju alagbara: li ododo ni ki iwọ ki o mã ṣe idajọ ẹnikeji rẹ.
16 Iwọ kò gbọdọ lọ soke lọ sodo bi olofófo lãrin awọn enia rẹ: bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ró tì ẹ̀jẹ ẹnikeji rẹ: Emi li OLUWA.
17 Iwọ kò gbọdọ korira arakunrin rẹ li ọkàn rẹ: ki iwọ ki o bá ẹnikeji rẹ wi, ki iwọ ki o máṣe jẹbi nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀.