12 Ẹnyin kò si gbọdọ fi orukọ mi bura eké, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ bà orukọ Ọlọrun rẹ jẹ́: Emi li OLUWA.
13 Iwọ kò gbọdọ rẹ́ ẹnikeji rẹ jẹ, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ jẹ haramu: owo ọ̀ya alagbaṣe kò gbọdọ sùn ọdọ rẹ titi di owurọ̀.
14 Iwọ kò gbọdọ bú aditi, tabi ki o fi ohun idugbolu siwaju afọju, ṣugbọn ki iwọ ki o bẹ̀ru Ọlọrun rẹ: Emi li OLUWA.
15 Ẹnyin kò gbọdọ ṣe aiṣododo ni idajọ: iwọ kò gbọdọ gbè talaka, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ṣe ojusaju alagbara: li ododo ni ki iwọ ki o mã ṣe idajọ ẹnikeji rẹ.
16 Iwọ kò gbọdọ lọ soke lọ sodo bi olofófo lãrin awọn enia rẹ: bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ró tì ẹ̀jẹ ẹnikeji rẹ: Emi li OLUWA.
17 Iwọ kò gbọdọ korira arakunrin rẹ li ọkàn rẹ: ki iwọ ki o bá ẹnikeji rẹ wi, ki iwọ ki o máṣe jẹbi nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀.
18 Iwọ kò gbọdọ gbẹsan, bẹ̃ni ki o máṣe ṣe ikùnsinu si awọn ọmọ enia rẹ, ṣugbọn ki iwọ ki o fẹ́ ẹnikeji rẹ bi ara rẹ: Emi li OLUWA.