31 Máṣe yipada tọ̀ awọn ti o ní ìmọ afọṣẹ, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o má si ṣe wá ajẹ́ kiri, lati fi wọn bà ara nyin jẹ́: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.
32 Ki iwọ ki o si dide duro niwaju ori-ewú, ki o si bọ̀wọ fun oju arugbo, ki o si bẹ̀ru Ọlọrun rẹ: Emi li OLUWA.
33 Ati bi alejò kan ba nṣe atipo pẹlu rẹ ni ilẹ nyin, ẹnyin kò gbọdọ ni i lara.
34 Ki alejò ti mbá nyin gbé ki o jasi fun nyin bi ibilẹ, ki iwọ ki o si fẹ́ ẹ bi ara rẹ; nitoripe ẹnyin ti ṣe alejò ni ilẹ Egipti: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.
35 Ẹnyin kò gbọdọ ṣe aiṣododo ni idajọ, ni ìwọn ọpá, ni òṣuwọn iwuwo, tabi ni òṣuwọn oninu.
36 Oṣuwọn otitọ, òṣuwọn iwuwo otitọ, òṣuwọn efa otitọ, ati òṣuwọn hini otitọ, ni ki ẹnyin ki o ní: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin, ti o mú nyin lati ilẹ Egipti jade wá.
37 Nitorina ni ki ẹnyin ki o si ma kiyesi gbogbo ìlana mi, ati si gbogbo idajọ mi, ki ẹnyin si ma ṣe wọn: Emi li OLUWA.