1 NIGBATI ẹnikan ba si nta ọrẹ-ẹbọ ohunjijẹ fun OLUWA, ki ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ ki o jẹ ti iyẹfun daradara; ki o si dà oróro sori rẹ̀, ki o si fi turari sori rẹ̀.
2 Ki o si mú u tọ̀ awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni wá: ki alufa si bù ikunwọ kan ninu rẹ̀, ninu iyẹfun na, ati ninu oróro na, pẹlu gbogbo turari rẹ̀; ki o si sun ẹbọ-iranti rẹ̀ lori pẹpẹ, lati ṣe ẹbọ ti a fi iná ṣe, õrùn didùn si OLUWA:
3 Iyokù ti ẹbọ ohunjijẹ na, a si jẹ ti Aaroni, ati ti awọn ọmọ rẹ̀: ohun mimọ́ julọ lati inu ẹbọ OLUWA ni ti a fi iná ṣe.
4 Bi iwọ ba si mú ọrẹ-ẹbọ ohunjijẹ wá, ti a yan ninu àro, ki o jẹ́ àkara alaiwu iyẹfun didara, ti a fi oróro pò, tabi àkara fẹlẹfẹlẹ alaiwu ti a ta oróro si.