13 Ati gbogbo ọrẹ-ẹbọ ohunjijẹ rẹ ni ki iwọ ki o fi iyọ̀ dùn; bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ jẹ ki iyọ̀ majẹmu Ọlọrun rẹ ki o má sí ninu ẹbọ ohunjijẹ rẹ: gbogbo ọrẹ-ẹbọ rẹ ni ki iwọ ki o fi iyọ̀ si.
14 Bi iwọ ba si mú ẹbọ ohunjijẹ akọ́so rẹ wá fun OLUWA, ki iwọ ki o si mú ṣiri ọkà daradara ti a yan lori iná wá fun ẹbọ ohunjijẹ akọ́so rẹ, ọkà gigún, ti ṣiri tutù.
15 Ki iwọ ki o si fi oróro sori rẹ̀, ki o si fi turari sori rẹ̀: ẹbọ ohunjijẹ ni.
16 Ki alufa ki o si sun ẹbọ-iranti rẹ̀, apakan ninu ọkà gigún rẹ̀, ati apakan ninu oróro rẹ̀, pẹlu gbogbo turari rẹ̀: ẹbọ ti a fi iná ṣe ni si OLUWA.