2 Ki o si mú u tọ̀ awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni wá: ki alufa si bù ikunwọ kan ninu rẹ̀, ninu iyẹfun na, ati ninu oróro na, pẹlu gbogbo turari rẹ̀; ki o si sun ẹbọ-iranti rẹ̀ lori pẹpẹ, lati ṣe ẹbọ ti a fi iná ṣe, õrùn didùn si OLUWA:
3 Iyokù ti ẹbọ ohunjijẹ na, a si jẹ ti Aaroni, ati ti awọn ọmọ rẹ̀: ohun mimọ́ julọ lati inu ẹbọ OLUWA ni ti a fi iná ṣe.
4 Bi iwọ ba si mú ọrẹ-ẹbọ ohunjijẹ wá, ti a yan ninu àro, ki o jẹ́ àkara alaiwu iyẹfun didara, ti a fi oróro pò, tabi àkara fẹlẹfẹlẹ alaiwu ti a ta oróro si.
5 Ati bi ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ ba ṣe ohunjijẹ, ti a ṣe ninu awopẹtẹ, ki o jẹ́ ti iyẹfun didara alaiwu, ti a fi òróró pò.
6 Ki iwọ ki o si dá a kelekele, ki o si dà oróro sori rẹ̀: ẹbọ ohunjijẹ ni.
7 Ati bi ọrẹ-ẹbọ rẹ ba ṣe ẹbọ ohunjijẹ, ti a yan ninu apẹ, iyẹfun didara ni ki a fi ṣe e pẹlu oróro.
8 Ki iwọ ki o si mú ẹbọ ohunjijẹ na wá, ti a fi nkan wọnyi ṣe fun OLUWA: on o si mú u tọ̀ alufa na wá, ki on ki o si mú u wá sori pẹpẹ nì.