1 OLUWA si sọ fun Mose pe, Sọ fun awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni, ki o si wi fun wọn pe, Ẹnikẹni ninu awọn enia rẹ̀ kò gbọdọ di alaimọ́ nitori okú.
2 Bikoṣe fun ibatan rẹ̀ ti o sunmọ ọ, eyinì ni, iya rẹ̀, ati baba rẹ̀, ati ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati ọmọ rẹ̀ obinrin, ati arakunrin rẹ̀;
3 Ati arabinrin rẹ̀ ti iṣe wundia, ti o wà lọdọ rẹ̀, ti kò ti ilí ọkọ, nitori rẹ̀ ni ki o di alaimọ́.
4 Ṣugbọn on kò gbọdọ ṣe ara rẹ̀ li aimọ́, lati bà ara rẹ̀ jẹ́, olori kan sa ni ninu awọn enia rẹ̀.
5 Nwọn kò gbọdọ dá ori wọn fá, bẹ̃ni nwọn kò gbọdọ tọ́ irungbọn wọn, tabi singbẹrẹ kan si ara wọn.
6 Ki nwọn ki o si jasi mimọ́ fun Ọlọrun wọn, ki nwọn ki o má si ṣe bà orukọ Ọlọrun wọn jẹ́: nitoripe ẹbọ OLUWA ti a fi ina ṣe, ati àkara Ọlọrun wọn, ni nwọn fi nrubọ: nitorina ni ki nwọn ki o jẹ́ mimọ́.