23 OLUWA si sọ fun Mose pe,
24 Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Li oṣù keje, li ọjọ́ kini oṣù ni ki ẹnyin ki o ní isimi; iranti ifunpe, apejọ mimọ́.
25 Ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara kan: bikoṣepe ki ẹnyin ki o ru ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA.
26 OLUWA si sọ fun Mose pe,
27 Ijọ́ kẹwa oṣù keje yi ni ki o ṣe ọjọ́ ètutu: ki apejọ mimọ́ wà fun nyin, ki ẹnyin ki o si pọ́n ọkàn nyin loju, ki ẹ si ru ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA.
28 Ẹnyin kò si gbọdọ ṣe iṣẹ kan li ọjọ́ na yi: nitoripe ọjọ́ ètutu ni, lati ṣètutu fun nyin niwaju OLUWA Ọlọrun nyin.
29 Nitoripe ọkànkọkàn ti kò ba pọ́n ara rẹ̀ loju li ọjọ́ na yi, on li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀.