30 Ati ọkànkọkan ti o ba ṣe iṣẹ kan li ọjọ́ na yi, ọkàn na li emi o run kuro lãrin awọn enia rẹ̀.
31 Ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹkiṣẹ kan: ki o jẹ́ ìlana titilai ni iran-iran nyin ni ibujoko nyin gbogbo.
32 Ọjọ́-isimi ni fun nyin, ki ẹnyin ki o si pọn ọkàn nyin loju: lo ọjọ́ kẹsan oṣù na li alẹ, lati alẹ dé alẹ, ni ki ẹnyin ki o ma pa ọjọ́-isimi nyin mọ́.
33 OLUWA si sọ fun Mose pe,
34 Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Ọjọ́ kẹdogun oṣù keje yi li ajọ agọ́ ni ijọ́ meje si OLUWA.
35 Li ọjọ́ kini li apejọ mimọ́: ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara kan.
36 Ijọ meje ni ki ẹnyin fi ru ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA: ni ijọ́ kẹjọ li apejọ́ mimọ́ fun nyin; ki ẹnyin ki o si ru ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA; ọjọ́ ajọ ni; ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara kan.