34 Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Ọjọ́ kẹdogun oṣù keje yi li ajọ agọ́ ni ijọ́ meje si OLUWA.
35 Li ọjọ́ kini li apejọ mimọ́: ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara kan.
36 Ijọ meje ni ki ẹnyin fi ru ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA: ni ijọ́ kẹjọ li apejọ́ mimọ́ fun nyin; ki ẹnyin ki o si ru ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA; ọjọ́ ajọ ni; ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara kan.
37 Wọnyi li ajọ OLUWA, ti ẹnyin o kedé lati jẹ́ apejọ mimọ́, lati ru ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA, ẹbọ sisun, ati ẹbọ ohunjijẹ, ẹbọ, ati ẹbọ ohunmimu, olukuluku wọn li ọjọ́ rẹ̀:
38 Pẹlu ọjọ́-isimi OLUWA, ati pẹlu ẹ̀bun nyin, ati pẹlu gbogbo ẹjẹ́ nyin, ati pẹlu gbogbo ẹbọ atinuwá nyin ti ẹnyin fi fun OLUWA.
39 Pẹlupẹlu li ọjọ́ kẹdogun oṣù keje na, nigbati ẹnyin ba ṣe ikore eso ilẹ tán, ki ẹnyin ki o si ṣe ajọ si OLUWA ni ijọ́ meje: li ọjọ́ kini ki isimi ki o wà, ati li ọjọ́ kẹjọ ki isimi ki o wà,
40 Li ọjọ́ kini ki ẹnyin ki o si mú eso igi daradara, imọ̀-ọpẹ, ati ẹká igi ti o bò, ati ti igi wilo odò; ki ẹnyin ki o si ma yọ̀ niwaju OLUWA Ọlọrun nyin ni ijọ́ meje.