40 Li ọjọ́ kini ki ẹnyin ki o si mú eso igi daradara, imọ̀-ọpẹ, ati ẹká igi ti o bò, ati ti igi wilo odò; ki ẹnyin ki o si ma yọ̀ niwaju OLUWA Ọlọrun nyin ni ijọ́ meje.
41 Ki ẹnyin ki o si ma pa a mọ́ li ajọ fun OLUWA ni ijọ́ meje li ọdún: ìlana ni titilai ni iran-iran nyin: ki ẹnyin ki o ma ṣe e li oṣù keje.
42 Ki ẹnyin ki o ma gbé inu agọ́ ni ijọ́ meje; gbogbo ibilẹ ni Israeli ni ki o gbé inu agọ́:
43 Ki iran-iran nyin ki o le mọ̀ pe, Emi li o mu awọn ọmọ Israeli gbé inu agọ́, nigbati mo mú wọn lati ilẹ Egipti jade wá: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.
44 Mose si sọ gbogbo ajọ OLUWA wọnyi fun awọn ọmọ Israeli.