5 Ni ijọ́ kẹrinla oṣù kini, li aṣalẹ, li ajọ irekọja OLUWA.
6 Ati li ọjọ́ kẹdogun oṣù na li ajọ àkara alaiwu si OLUWA: ijọ́ meje li ẹnyin o jẹ àkara alaiwu.
7 Li ọjọ́ kini ki ẹnyin ki o ní apejọ mimọ́: ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara ninu rẹ̀.
8 Bikoṣe ki ẹnyin ki o ru ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA ni ijọ́ meje: ni ijọ́ keje ni apejọ mimọ́: ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara.
9 OLUWA si sọ fun Mose pe,
10 Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba dé ilẹ ti mo fi fun nyin, ti ẹnyin o si ma ṣe ikore rẹ̀, nigbana ni ki ẹnyin ki o mú ìdi-ọkà kan akọ́so ikore nyin tọ̀ alufa wá:
11 On o si fì ìdi-ọkà na niwaju OLUWA, lati ṣe itẹwọgbà fun nyin: ni ijọ́ keji lẹhin ọjọ́-isimi ni ki alufa ki o fì i.