18 Nitorina ki ẹnyin ki o ma ṣe ìlana mi, ki ẹ si ma pa ofin mi mọ́, ki ẹ si ma ṣe wọn; ẹnyin o si ma gbé ilẹ na li ailewu.
19 Ilẹ na yio si ma mú ibisi rẹ̀ wá, ẹ o si ma jẹ ajẹyo, ẹ o si ma gbé inu rẹ̀ li ailewu.
20 Bi ẹnyin ba si wipe, Kili awa o ha ma jẹ li ọdún keje? sa wo o, awa kò gbọdọ gbìn, bẹ̃li awa kò gbọdọ kó ire wa:
21 Nigbana li emi o fi aṣẹ ibukún mi fun nyin li ọdún kẹfa, on o si so eso jade fun nyin fun ọdún mẹta.
22 Ẹnyin o si gbìn li ọdún kẹjọ, ẹnyin o si ma jẹ ninu eso lailai titi di ọdún kẹsan, titi eso rẹ̀ yio fi dé ni ẹnyin o ma jẹ ohun isigbẹ.
23 Ẹnyin kò gbọdọ tà ilẹ lailai; nitoripe ti emi ni ilẹ: nitoripe alejò ati atipo ni nyin lọdọ mi.
24 Ati ni gbogbo ilẹ-iní nyin ki ẹnyin ki o si ma ṣe ìrapada fun ilẹ.