12 Emi o si ma rìn lãrin nyin, emi o si ma ṣe Ọlọrun nyin, ẹnyin o si ma ṣe enia mi.
13 Emi li OLUWA Ọlọrun nyin ti o mú nyin lati ilẹ Egipti jade wá, ki ẹnyin ki o máṣe wà li ẹrú wọn; emi si ti dá ìde àjaga nyin, mo si mu nyin rìn lõrogangan.
14 Ṣugbọn bi ẹnyin kò ba gbọ́ ti emi, ti ẹ kò si ṣe gbogbo ofin wọnyi;
15 Bi ẹnyin ba si gàn ìlana mi, tabi bi ọkàn nyin ba korira idajọ mi, tobẹ̃ ti ẹnyin ki yio fi ṣe gbogbo ofin mi, ṣugbọn ti ẹnyin dà majẹmu mi;
16 Emi pẹlu yio si ṣe eyi si nyin; emi o tilẹ rán ẹ̀ru si nyin, àrun-igbẹ ati òjojo gbigbona, ti yio ma jẹ oju run, ti yio si ma mú ibinujẹ ọkàn wá: ẹnyin o si fun irugbìn nyin lasan, nitoripe awọn ọtá nyin ni yio jẹ ẹ.
17 Emi o si kọ oju mi si nyin, a o si pa nyin niwaju awọn ọtá nyin: awọn ti o korira nyin ni yio si ma ṣe olori nyin; ẹnyin o si ma sá nigbati ẹnikan kò lé nyin.
18 Ninu gbogbo eyi, bi ẹnyin kò ba si gbọ́ ti emi, nigbana li emi o jẹ nyin ni ìya ni ìgba meje si i nitori ẹ̀ṣẹ nyin.