30 Emi o si run ibi giga nyin wọnni, emi o si ke ere nyin lulẹ, emi o si wọ́ okú nyin sori okú oriṣa nyin; ọkàn mi yio si korira nyin.
31 Emi o si sọ ilu nyin di ahoro, emi o si sọ ibi mimọ́ nyin di ahoro, emi ki yio gbọ́ adùn õrùn didùn nyin mọ́.
32 Emi o si sọ ilẹ na di ahoro: ẹnu yio si yà awọn ọtá nyin ti ngbé inu rẹ̀ si i.
33 Emi o si tú nyin ká sinu awọn orilẹ-ède, emi o si yọ idà tì nyin lẹhin: ilẹ nyin yio si di ahoro, ati ilu nyin yio di ahoro.
34 Nigbana ni ilẹ na yio ní isimi rẹ̀, ni gbogbo ọjọ́ idahoro rẹ̀, ẹnyin o si wà ni ilẹ awọn ọtá nyin; nigbana ni ilẹ yio simi, ti yio si ní isimi rẹ̀.
35 Ni gbogbo ọjọ́ idahoro rẹ̀ ni yio ma simi; nitoripe on kò simi li ọjọ́-isimi nyin, nigbati ẹnyin ngbé inu rẹ̀.
36 Ati lara awọn ti o kù lãye ninu nyin, li emi o rán ijàiya si ọkàn wọn ni ilẹ awọn ọtá wọn: iró mimì ewé yio si ma lé wọn; nwọn o si sá, bi ẹni sá fun idà; nwọn o si ma ṣubu nigbati ẹnikan kò lepa.