37 Nwọn o si ma ṣubulù ara wọn, bi ẹnipe niwaju idà, nigbati kò sí ẹniti nlepa: ẹnyin ki yio si lí agbara lati duro niwaju awọn ọtá nyin.
38 Ẹnyin o si ṣegbé ninu awọn orilẹ-ède, ilẹ awọn ọtá nyin yio si mú nyin jẹ.
39 Ati awọn ti o kù ninu nyin yio si joro ninu ẹ̀ṣẹ wọn ni ilẹ awọn ọtá nyin; ati nitori ẹ̀ṣẹ awọn baba wọn pẹlu ni nwọn o ma joro pẹlu wọn.
40 Bi nwọn ba si jẹwọ irekọja wọn, ati irekọja awọn baba wọn, pẹlu ọ̀tẹ wọn ti nwọn ti ṣe si mi, ati pẹlu nitoripe nwọn ti rìn lodi si mi;
41 Emi pẹlu rìn lodi si wọn, mo si mú wọn wá si ilẹ awọn ọtá wọn: njẹ bi àiya wọn alaikọlà ba rẹ̀silẹ, ti nwọn ba si gbà ibawi ẹ̀ṣẹ wọn;
42 Nigbana li emi o ranti majẹmu mi pẹlu Jakobu; ati majẹmu mi pẹlu Isaaki, ati majẹmu mi pẹlu Abrahamu li emi o ranti; emi o si ranti ilẹ na.
43 Nwọn o si fi ilẹ na silẹ, on o si ní isimi rẹ̀, nigbati o ba di ahoro li aisí wọn; nwọn o si gbà ibawi ẹ̀ṣẹ wọn: nitoripe, ani nitoripe nwọn gàn idajọ mi, ati ọkàn wọn korira ìlana mi.