40 Bi nwọn ba si jẹwọ irekọja wọn, ati irekọja awọn baba wọn, pẹlu ọ̀tẹ wọn ti nwọn ti ṣe si mi, ati pẹlu nitoripe nwọn ti rìn lodi si mi;
41 Emi pẹlu rìn lodi si wọn, mo si mú wọn wá si ilẹ awọn ọtá wọn: njẹ bi àiya wọn alaikọlà ba rẹ̀silẹ, ti nwọn ba si gbà ibawi ẹ̀ṣẹ wọn;
42 Nigbana li emi o ranti majẹmu mi pẹlu Jakobu; ati majẹmu mi pẹlu Isaaki, ati majẹmu mi pẹlu Abrahamu li emi o ranti; emi o si ranti ilẹ na.
43 Nwọn o si fi ilẹ na silẹ, on o si ní isimi rẹ̀, nigbati o ba di ahoro li aisí wọn; nwọn o si gbà ibawi ẹ̀ṣẹ wọn: nitoripe, ani nitoripe nwọn gàn idajọ mi, ati ọkàn wọn korira ìlana mi.
44 Ṣugbọn sibẹ̀ ninu gbogbo eyina, nigbati nwọn ba wà ni ilẹ awọn ọtá wọn, emi ki yio tà wọn nù, bẹ̃li emi ki yio korira wọn, lati run wọn patapata, ati lati dà majẹmu mi pẹlu wọn: nitoripe Emi li OLUWA Ọlọrun wọn:
45 Ṣugbọn nitori wọn emi o ranti majẹmu awọn baba nla wọn, ti mo mú lati ilẹ Egipti jade wá li oju awọn orilẹ-ède, ki emi ki o le ma ṣe Ọlọrun wọn: Emi li OLUWA.
46 Wọnyi ni ìlana ati idajọ, ati ofin ti OLUWA dásilẹ, lãrin on ati awọn ọmọ Israeli li òke Sinai nipa ọwọ́ Mose.