2 Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati enia kan ba jẹ́ ẹjẹ́ pataki kan, ki awọn enia na ki o jẹ́ ti OLUWA gẹgẹ bi idiyelé rẹ.
3 Idiyelé rẹ fun ọkunrin yio si jẹ́ lati ẹni ogún ọdún lọ titi di ọgọta ọdún, idiyelé rẹ yio si jẹ́ ãdọta ṣekeli fadakà, gẹgẹ bi ṣekeli ibi mimọ́.
4 Bi on ba si ṣe obinrin, njẹ ki idiyelé rẹ ki o jẹ́ ọgbọ̀n ṣekeli.
5 Bi o ba si ṣepe lati ọmọ ọdún marun lọ, titi di ẹni ogún ọdún, njẹ ki idiyelé rẹ ki o jẹ́ ogún ṣekeli fun ọkunrin, ati fun obinrin ṣekeli mẹwa.
6 Bi o ba si ṣepe lati ọmọ oṣù kan lọ titi di ọmọ ọdún marun, njẹ ki idiyelé rẹ fun ọkunrin ki o jẹ́ ṣekeli fadakà marun, ati fun obinrin, idiyelé rẹ yio jẹ ṣekeli fadakà mẹta.
7 Bi o ba si ṣe lati ẹni ọgọta ọdún lọ tabi jù bẹ̃ lọ; bi o ba jẹ́ ọkunrin, njẹ ki idiyelé rẹ ki o jẹ́ ṣekeli mẹdogun, ati fun obinrin ṣekeli mẹwa.
8 Ṣugbọn bi on ba ṣe talakà jù idiyele lọ, njẹ ki o lọ siwaju alufa, ki alufa ki o diyelé e; gẹgẹ bi agbara ẹniti o jẹ́ ẹjẹ́ na ni ki alufa ki o diyelé e.