1 BI ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ ba si ṣe ẹbọ alafia, bi o ba mú u lati inu ọwọ́-ẹran wá, on iba ṣe akọ tabi abo, ki o mú u wá siwaju OLUWA li ailabùku.
2 Ki o si fi ọwọ́ rẹ̀ lé ori ọrẹ-ẹbọ rẹ̀, ki o si pa a li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ: ki awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni ki o si fi ẹ̀jẹ na wọ́n ori pẹpẹ nì yiká.
3 Ki o si mú ninu ẹbọ alafia nì wá, ọrẹ-ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA; ọrá ti o bò ifun lori, ati gbogbo ọrá ti mbẹ lara ifun na.
4 Ati iwe nì mejeji, ati ọrá ti mbẹ́ lara wọn, ti mbẹ li ẹba ìha, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ, pẹlu iwe nì, on ni ki o mú kuro.
5 Ki awọn ọmọ Aaroni ki o si sun u lori pẹpẹ nì lori ẹbọ sisun, ti mbẹ lori igi ti o wà lori iná: ẹbọ ti a fi iná ṣe ni, õrùn didùn si OLUWA.
6 Bi ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ fun ọrẹ-ẹbọ alafia si OLUWA ba ṣe ti agbo-ẹran; akọ tabi abo, ki o mú u wá li ailabùku.