23 Tabi bi ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ninu eyiti o ti ṣẹ̀, ba di mímọ̀ fun u; ki o mú ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ wá, ọmọ ewurẹ kan, akọ alailabùku:
24 Ki o si fi ọwọ́ rẹ̀ lé ori ewurẹ na, ki o si pa a ni ibiti nwọn gbé npa ẹbọ sisun niwaju OLUWA: ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni.
25 Ki alufa na ki o si fi iká rẹ̀ mú ninu ẹ̀jẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ na, ki o si fi i sara iwo pẹpẹ ẹbọsisun, ki o si dà ẹ̀jẹ si isalẹ pẹpẹ ẹbọsisun.
26 Ki o si sun gbogbo ọrá rẹ̀ li ori pẹpẹ, bi ti ọrá ẹbọ alafia: ki alufa ki o si ṣètutu fun u nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀, a o si dari rẹ̀ jì i.
27 Bi ọkan ninu awọn enia ilẹ na ba fi aimọ̀ sẹ̀, nigbati o ba ṣì ohun kan ṣe si ọkan ninu ofin OLUWA ti a ki ba ṣe, ti o si jẹbi;
28 Tabi bi ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ti o ti ṣẹ̀, ba di mimọ̀ fun u, nigbana ni ki o mú ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ wá, ọmọ ewurẹ kan, abo alailabùku, nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ti ṣẹ̀.
29 Ki o si fi ọwọ́ rẹ̀ lé ori ẹbọ ẹ̀ṣẹ na, ki o si pa ẹbọ ẹ̀ṣẹ na ni ibi ẹbọsisun.