5 Ki alufa na ti a fi oróro yàn, ki o bù ninu ẹ̀jẹ akọmalu na, ki o si mú u wá si agọ́ ajọ:
6 Ki alufa na ki o tẹ̀ iká rẹ̀ bọ̀ inu ẹ̀jẹ na, ki o si fi ninu ẹ̀jẹ na wọ́n nkan nigba meje niwaju OLUWA, niwaju aṣọ-ikele ibi mimọ́.
7 Ki alufa ki o si fi diẹ ninu ẹ̀jẹ na sara iwo pẹpẹ turari didùn niwaju OLUWA, eyiti mbẹ ninu agọ́ ajọ; ki o si dà gbogbo ẹ̀jẹ akọmalu nì si isalẹ pẹpẹ ẹbọsisun, ti mbẹ li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ.
8 Ki o si mú gbogbo ọrá akọmalu nì fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ kuro lara rẹ̀; ọrá ti o bò ifun lori, ati gbogbo ọrá ti mbẹ lara ifun na,
9 Ati iwe mejeji, ati ọrá ti mbẹ lara wọn, ti mbẹ lẹba ìha, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ, pẹlu iwe, on ni ki o mú kuro,
10 Bi a ti mú u kuro lara akọmalu ẹbọ-ọrẹ ẹbọ alafia: ki alufa ki o si sun wọn lori pẹpẹ ẹbọsisun.
11 Ati awọ akọmalu na, ati gbogbo ẹran rẹ̀, pẹlu ori rẹ̀, ati pẹlu itan rẹ̀, ati ifun rẹ̀, ati igbẹ́ rẹ̀,