1 OLUWA si sọ fun Mose pe,
2 Bi ẹnikan ba ṣẹ̀, ti o dẹ̀ṣẹ si OLUWA, ti o si sẹ́ fun ẹnikeji rẹ̀, li ohun ti o fi fun u pamọ́, tabi li ohun ti a fi dógo, tabi ohun ti a fi agbara gbà, tabi ti o rẹ ẹnikeji rẹ̀ jẹ;
3 Tabi ti o ri ohun ti o nù he, ti o si ṣeké nitori rẹ̀, ti o si bura eké; li ọkan ninu gbogbo ohun ti enia ṣe, ti o ṣẹ̀ ninu rẹ̀:
4 Yio si ṣe, bi o ba ti ṣẹ̀, ti o si jẹbi, ki o si mú ohun ti o fi agbara gbà pada, tabi ohun ti o fi irẹjẹ ní, tabi ohun ti a fi fun u pamọ́, tabi ohun ti o nù ti o rihe.
5 Tabi gbogbo eyi na nipa eyiti o bura eké; ki o tilẹ mú u pada li oju-owo rẹ̀, ki o si fi idamarun rẹ̀ lé ori rẹ̀, ki o si fi i fun olohun, li ọjọ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ rẹ̀.