12 Ki iná ori pẹpẹ nì ki o si ma jó lori rẹ̀; ki a máṣe pa a; ki alufa ki o si ma kòná igi lori rẹ̀ li orowurọ̀, ki o si tò ẹbọ sisun sori rẹ̀; ki o si ma sun ọrá ẹbọ alafia lori rẹ̀.
13 Ki iná ki o ma jó titi lori pẹpẹ na; kò gbọdọ kú lai.
14 Eyi si li ofin ẹbọ ohunjijẹ: ki awọn ọmọ Aaroni ki o ru u niwaju OLUWA, niwaju pẹpẹ.
15 Ki o si bù ikunwọ rẹ̀ kan ninu rẹ̀, ninu iyẹfun didara ẹbọ ohunjijẹ na, ati ti oróro rẹ̀, ati gbogbo turari ti mbẹ lori ẹbọ ohunjijẹ, ki o si sun u lori pẹpẹ fun õrùn didùn, ani fun iranti rẹ̀, si OLUWA.
16 Iyokù rẹ̀ ni Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ yio jẹ: àkara alaiwu ni, ki a jẹ ẹ ni ibi mimọ́; ni agbalá agọ́ ajọ ni ki nwọn ki o jẹ ẹ.
17 Ki a máṣe fi iwukàra yan a. Mo ti fi i fun wọn ni ipín ti wọn ninu ẹbọ mi ti a fi iná ṣe; mimọ́ julọ ni, bi ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati bi ẹbọ ẹbi.
18 Gbogbo awọn ọkunrin ninu awọn ọmọ Aaroni ni ki o jẹ ninu rẹ̀, yio jasi aṣẹ titilai ni iraniran nyin, nipa ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe: ẹnikẹni ti o ba kàn wọn yio di mimọ́.