13 Pẹlu adidùn àkara wiwu ki o mú ọrẹ-ẹbọ pẹlu ẹbọ alafia rẹ̀ wa fun idupẹ́.
14 Ati ninu rẹ̀ ni ki o mú ọkan kuro ninu gbogbo ọrẹ-ẹbọ na fun ẹbọ agbesọsoke si OLUWA; ki o si jẹ́ ti alufa ti o nwọ́n ẹ̀jẹ ẹbọ alafia.
15 Ati ẹran ẹbọ alafia rẹ̀ fun idupẹ́, ki a jẹ ẹ li ọjọ́ na ti a fi rubọ; ki o máṣe kù ninu rẹ̀ silẹ titi di owurọ̀.
16 Ṣugbọn bi ẹbọ-ọrẹ rẹ̀ ba ṣe ti ẹjẹ́, tabi ọrẹ-ẹbọ atinuwá, ki a jẹ ẹ li ọjọ́ na ti o ru ẹbọ rẹ̀: ati ni ijọ́ keji ni ki a jẹ iyokù rẹ̀ pẹlu:
17 Ṣugbọn iyokù ninu ẹran ẹbọ na ni ijọ́ kẹta ni ki a fi iná sun.
18 Bi a ba si jẹ ninu ẹran ẹbọ alafia rẹ̀ rára ni ijọ́ kẹta, ki yio dà, bẹ̃li a ki yio kà a si fun ẹniti o ru u: irira ni yio jasi, ọkàn ti o ba si jẹ ẹ yio rù ẹ̀ṣẹ rẹ̀.
19 Ẹran ti o ba si kàn ohun aimọ́ kan, a kò gbọdọ jẹ ẹ; sisun ni ki a fi iná sun u. Ṣugbọn ẹran na ni, gbogbo ẹniti o mọ́ ni ki o jẹ ninu rẹ̀.