31 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Sebuluni, o jẹ́ ẹgbã mejidilọgbọ̀n o le egbeje.
32 Ti awọn ọmọ Josefu, eyinì ni, ti awọn ọmọ Efraimu, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun;
33 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Efraimu, o jẹ́ ọkẹ meji o le ẹdẹgbẹta.
34 Ti awọn ọmọ Manasse, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun;
35 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Manasse, o jẹ́ ẹgba mẹrindilogun o le igba.
36 Ti awọn ọmọ Benjamini, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun;
37 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Benjamini, o jẹ́ ẹgba mẹtadilogun o le egbeje.