39 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Dani, o jẹ́ ẹgbã mọkanlelọgbọ̀n o le ẹdẹgbẹrin.
40 Ti awọn ọmọ Aṣeri, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun;
41 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Aṣeri, o jẹ́ ọkẹ meji o le ẹdẹgbẹjọ.
42 Ti awọn ọmọ Naftali, iran wọn, nipa idile wọn, nipa ile baba wọn, gẹgẹ bi iye orukọ, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun;
43 Awọn ti a kà ninu wọn, ninu ẹ̀ya Naftali, o jẹ́ ẹgba mẹrindilọgbọ̀n o le egbeje.
44 Wọnyi li awọn ti a kà, ti Mose ati Aaroni kà, ati awọn olori Israeli, ọkunrin mejila: olukuluku wà fun ile awọn baba rẹ̀.
45 Bẹ̃ni gbogbo awọn ti a kà ninu awọn ọmọ Israeli, nipa ile baba wọn, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ, gbogbo awọn ti o le jade lọ si ogun ni Israeli;