51 Nigbati agọ́ na ba si ṣí siwaju, ki awọn ọmọ Lefi ki o tú u palẹ: nigbati nwọn o ba si pa agọ́ na, awọn ọmọ Lefi ni ki o gbé e duro: alejó ti o ba sunmọtosi, pipa ni.
52 Ki awọn ọmọ Israeli ki o si pa agọ́ wọn, olukuluku ni ibudó rẹ̀, ati olukuluku lẹba ọpagun rẹ̀, gẹgẹ bi ogun wọn.
53 Ṣugbọn awọn ọmọ Lefi ni ki o dó yi agọ́ erí na ká, ki ibinu ki o má ba si lara ijọ awọn ọmọ Israeli: ki awọn ọmọ Lefi ki o si ma ṣe itọju agọ́ ẹrí na.
54 Bayi ni awọn ọmọ Israeli si ṣe; gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA ti paṣẹ fun Mose, bẹ̃ni nwọn ṣe.