1 OLUWA si sọ fun Mose pe,
2 Iwọ ṣe ipè fadakà meji; iṣẹ́-ọnà lilù ni ki o ṣe wọn: iwọ o si ma fi wọn pè ajọ, iwọ o si ma fi wọn ṣí ibudó.
3 Nigbati nwọn ba fun wọn, ki gbogbo ijọ ki o pé sọdọ rẹ li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ.
4 Bi o ba ṣepe ipè kan ni nwọn fun, nigbana ni ki awọn ijoye, olori ẹgbẹgbẹrun enia Israeli, ki o pejọ sọdọ rẹ.
5 Nigbati ẹnyin ba si fun ipè idagiri, nigbana ni ki awọn ibudó ti o wà ni ìha ìla-õrùn ki o ṣí siwaju.
6 Nigbati ẹnyin ba si fun ipè idagiri nigba keji, nigbana ni ki awọn ibudó ti o wà ni ìha gusù ki o ṣì siwaju: ki nwọn ki o si fun ipè idagiri ṣíṣi wọn.