7 Ṣugbọn nigbati a o ba pè ijọ pọ̀, ki ẹ fun ipè, ṣugbọn ẹ kò gbọdọ fun ti idagiri.
8 Awọn ọmọ Aaroni, awọn alufa, ni ki o si fun ipè na; ki nwọn ki o si ma ṣe ìlana lailai fun nyin ni iran-iran nyin.
9 Bi ẹnyin ba si lọ si ogun ni ilẹ nyin lọ ipade awọn ọtá ti nni nyin lara, nigbana ni ki ẹnyin ki o fi ipè fun idagiri; a o si ranti nyin niwaju OLUWA Ọlọrun nyin, a o si gbà nyin lọwọ awọn ọtá nyin.
10 Li ọjọ̀ ayọ̀ nyin pẹlu, ati li ajọ nyin, ati ni ìbẹrẹ oṣù nyin, ni ki ẹnyin ki o fun ipè sori ẹbọ sisun nyin, ati sori ẹbọ ti ẹbọ alafia nyin; ki nwọn ki o le ma ṣe iranti fun nyin niwaju Ọlọrun nyin: Emi ni OLUWA Ọlọrun nyin.
11 O si ṣe li ogun ọjọ́ oṣù keji, li ọdún keji, ni awọsanma ká soke kuro lori agọ́ ẹrí.
12 Awọn ọmọ Israeli si dide ìrin wọn lati ijù Sinai; awọsanma na si duro ni ijù Parani.
13 Nwọn si bẹ̀rẹsi iṣí gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA nipa ọwọ́ Mose.