8 Awọn enia na a ma lọ kakiri, nwọn a si kó o, nwọn a si lọ̀ ọ ninu ọlọ, tabi nwọn a si gún u ninu odó, nwọn a si sè e ninu ìkoko, nwọn a si fi din àkara: itọwò rẹ̀ si ri bi itọwò àkara oróro.
9 Nigbati ìri ba si sẹ̀ si ibudó li oru, manna a bọ́ si i.
10 Nigbana ni Mose gbọ́, awọn enia nsọkun ni idile wọn, olukuluku li ẹnu-ọ̀na agọ́ tirẹ̀: ibinu OLUWA si rú si wọn gidigidi; o si buru loju Mose.
11 Mose si wi fun OLUWA pe, Nitori kini iwọ fi npọ́n iranṣẹ rẹ loju? nitori kili emi kò si ṣe ri ore-ọfẹ li oju rẹ, ti iwọ fi dì ẹrù gbogbo enia yi lé mi?
12 Iṣe emi li o lóyun gbogbo enia yi? iṣe emi li o bi wọn, ti iwọ fi wi fun mi pe, Ma gbé wọn lọ li õkanaiya rẹ, bi baba iti igbé ọmọ ọmú, si ilẹ ti iwọ ti bura fun awọn baba wọn.
13 Nibo li emi o gbé ti mú ẹran wá fi fun gbogbo enia yi? nitoriti nwọn nsọkun si mi wipe, Fun wa li ẹran, ki awa ki o jẹ.
14 Emi nikan kò le rù gbogbo awọn enia yi, nitoriti nwọn wuwo jù fun mi.