3 Ṣugbọn ọkunrin na Mose, o ṣe ọlọkàn tutù jù gbogbo enia lọ ti mbẹ lori ilẹ.
4 OLUWA si sọ fun Mose, ati fun Aaroni, ati fun Miriamu li ojiji pe, Ẹnyin mẹtẹta ẹ jade wá si agọ́ ajọ. Awọn mẹtẹta si jade.
5 OLUWA si sọkalẹ wá ninu ọwọ̀n awọsanma, o si duro li ẹnu-ọ̀na agọ́ na, o si pè Aaroni ati Miriamu: awọn mejeji si jade wá.
6 O si wipe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ mi nisisiyi: bi wolĩ OLUWA ba mbẹ ninu nyin, emi OLUWA yio farahàn fun u li ojuran, emi o si bá a sọ̀rọ li oju-alá.
7 Mose iranṣẹ mi kò ri bẹ̃, olõtọ ni ninu gbogbo ile mi.
8 On li emi mbá sọ̀rọ li ẹnu ko ẹnu, ati ni gbangba, ki si iṣe li ọ̀rọ ti o ṣe òkunkun; apẹrẹ OLUWA li on o si ri: njẹ nitori kili ẹnyin kò ṣe bẹ̀ru lati sọ̀rọ òdi si Mose iranṣẹ mi?
9 Ibinu OLUWA si rú si wọn; o si lọ.