6 O si wipe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ mi nisisiyi: bi wolĩ OLUWA ba mbẹ ninu nyin, emi OLUWA yio farahàn fun u li ojuran, emi o si bá a sọ̀rọ li oju-alá.
7 Mose iranṣẹ mi kò ri bẹ̃, olõtọ ni ninu gbogbo ile mi.
8 On li emi mbá sọ̀rọ li ẹnu ko ẹnu, ati ni gbangba, ki si iṣe li ọ̀rọ ti o ṣe òkunkun; apẹrẹ OLUWA li on o si ri: njẹ nitori kili ẹnyin kò ṣe bẹ̀ru lati sọ̀rọ òdi si Mose iranṣẹ mi?
9 Ibinu OLUWA si rú si wọn; o si lọ.
10 Awọsanma si lọ kuro lori Agọ́ na; si kiyesi i, Miriamu di adẹ̀tẹ, o fun bi òjo didì; Aaroni si wò Miriamu, si kiyesi i, o di adẹ̀tẹ.
11 Aaroni si wi fun Mose pe, Yẽ, oluwa mi, emi bẹ̀ ọ, máṣe kà ẹ̀ṣẹ na si wa lọrùn, eyiti awa fi wère ṣe, ati eyiti awa ti dẹ̀ṣẹ.
12 Emi bẹ̀ ọ máṣe jẹ ki o dabi ẹniti o kú, ẹniti àbọ ara rẹ̀ run tán nigbati o ti inu iya rẹ̀ jade.