2 Gbogbo awọn ọmọ Israeli si nkùn si Mose ati si Aaroni: gbogbo ijọ si wi fun wọn pe, Awa iba kuku ti kú ni ilẹ Egipti! tabi awa iba kú li aginjù yi!
3 Nitori kini OLUWA ṣe mú wa wá si ilẹ yi, lati ti ipa idà ṣubu? Awọn aya wa, ati awọn ọmọ wa yio di ijẹ: kò ha san fun wa ki a pada lọ si Egipti?
4 Nwọn si wi fun ara wọn pe, Ẹ jẹ ki a yàn olori, ki a si pada lọ si Egipti.
5 Nigbana ni Mose ati Aaroni doju wọn bolẹ niwaju gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli.
6 Ati Joṣua ọmọ Nuni ati Kalebu ọmọ Jefunne, ti o wà ninu awọn ti o ṣe amí ilẹ na, fà aṣọ wọn ya:
7 Nwọn si sọ fun gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, wipe, Ilẹ na ti awa là já lati ṣe amí rẹ̀, ilẹ na dara gidigidi.
8 Bi OLUWA ba fẹ́ wa, njẹ yio mú wa wọ̀ inu ilẹ na yi, yio si fi i fun wa; ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin.