37 Ani awọn ọkunrin na ti o mú ìhin buburu ilẹ na wá, nwọn ti ipa àrun kú niwaju OLUWA.
38 Ṣugbọn Joṣua ọmọ Nuni, ati Kalebu ọmọ Jefunne, ninu awọn ọkunrin na ti o rìn ilẹ na lọ, wà lãye.
39 Mose si sọ ọ̀rọ wọnyi fun gbogbo awọn ọmọ Israeli: awọn enia na si kãnu gidigidi.
40 Nwọn si dide ni kùtukutu owurọ̀, nwọn si gùn ori òke nì lọ, wipe, Kiyesi i, awa niyi, awa o si gòke lọ si ibiti OLUWA ti ṣe ileri: nitoripe awa ti ṣẹ̀.
41 Mose si wipe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nre aṣẹ OLUWA kọja? kì yio sa gbè nyin.
42 Ẹ máṣe gòke lọ, nitoriti OLUWA kò sí lãrin nyin, ki a má ba lù nyin bolẹ niwaju awọn ọtá nyin.
43 Nitoriti awọn ara Amaleki ati awọn ara Kenaani mbẹ niwaju nyin, ẹnyin o si ti ipa idà ṣubu: nitoriti ẹnyin ti yipada kuro lẹhin OLUWA, nitorina OLUWA ki yio si pẹlu nyin.