11 Mose si gbé ọwọ́ rẹ̀ soke, o si fi ọpá rẹ̀ lù apata na lẹ̃meji: omi si tú jade li ọ̀pọlọpọ, ijọ awọn enia si mu, ati ẹran wọn pẹlu.
12 OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe, Nitoriti ẹnyin kò gbà mi gbọ́, lati yà mi simimọ́ loju awọn ọmọ Israeli, nitorina ẹnyin ki yio mú ijọ awọn enia yi lọ si ilẹ na ti mo fi fun wọn.
13 Wọnyi li omi Meriba; nitoriti awọn ọmọ Israeli bá OLUWA sọ̀, o si di ẹni ìya-simimọ́ ninu wọn.
14 Mose si rán onṣẹ lati Kadeṣi si ọba Edomu, wipe, Bayi ni Israeli arakunrin rẹ wi, Iwọ sá mọ̀ gbogbo ìrin ti o bá wa:
15 Bi awọn baba wa ti sọkalẹ lọ si Egipti, ti awa si ti gbé Egipti ni ìgba pipẹ; awọn ara Egipti si ni wa lara, ati awọn baba wa:
16 Nigbati awa si kepè OLUWA, o gbọ́ ohùn wa, o si rán angeli kan, o si mú wa lati Egipti jade wá; si kiyesi i, awa mbẹ ni Kadeṣi, ilu kan ni ipinlẹ àgbegbe rẹ:
17 Jẹ ki awa ki o là ilẹ rẹ kọja lọ, awa bẹ̀ ọ: awa ki yio là inu oko rẹ, tabi inu ọgbà-àjara, bẹ̃li awa ki yio mu ninu omi kanga: ọ̀na opópo ọba li awa o gbà, awa ki o yà si ọwọ́ ọtún tabi si òsi, titi awa o fi kọja ipinlẹ rẹ.