13 Wọnyi li omi Meriba; nitoriti awọn ọmọ Israeli bá OLUWA sọ̀, o si di ẹni ìya-simimọ́ ninu wọn.
14 Mose si rán onṣẹ lati Kadeṣi si ọba Edomu, wipe, Bayi ni Israeli arakunrin rẹ wi, Iwọ sá mọ̀ gbogbo ìrin ti o bá wa:
15 Bi awọn baba wa ti sọkalẹ lọ si Egipti, ti awa si ti gbé Egipti ni ìgba pipẹ; awọn ara Egipti si ni wa lara, ati awọn baba wa:
16 Nigbati awa si kepè OLUWA, o gbọ́ ohùn wa, o si rán angeli kan, o si mú wa lati Egipti jade wá; si kiyesi i, awa mbẹ ni Kadeṣi, ilu kan ni ipinlẹ àgbegbe rẹ:
17 Jẹ ki awa ki o là ilẹ rẹ kọja lọ, awa bẹ̀ ọ: awa ki yio là inu oko rẹ, tabi inu ọgbà-àjara, bẹ̃li awa ki yio mu ninu omi kanga: ọ̀na opópo ọba li awa o gbà, awa ki o yà si ọwọ́ ọtún tabi si òsi, titi awa o fi kọja ipinlẹ rẹ.
18 Edomu si wi fun u pe, Iwọ ki yio kọja lọdọ mi, ki emi ki o má ba jade si ọ ti emi ti idà.
19 Awọn ọmọ Israeli si wi fun u pe, Ọ̀na opópo ọba li awa o gbà: bi awa ba mu ninu omi rẹ, emi ati ẹran mi, njẹ emi o san owo rẹ̀: laiṣe ohun miran, ki nsá fi ẹsẹ̀ mi là ilẹ kọja.