16 Lati ibẹ̀ nwọn si lọ si Beeri: eyinì ni kanga eyiti OLUWA sọ fun Mose pe, Pe awọn enia jọ, emi o si fun wọn li omi.
17 Nigbana ni Israeli kọrin yi pe: Sun jade iwọ kanga; ẹ ma kọrin si i:
18 Kanga na, ti awọn olori wà, ti awọn ọlọlá awọn enia si fi ọpá-alade na, ati ọpá wọn wà. Ati lati aginjù na, nwọn lọ si Mattana.
19 Ati Mattana nwọn lọ si Nahalieli: ati lati Nahalieli nwọn lọ si Bamotu:
20 Ati lati Bamotu li afonifoji nì, ti mbẹ ni ilẹ Moabu, si óke Pisga, ti o si kọjusi aginjù.
21 Israeli si rán onṣẹ si Sihoni ọba awọn ọmọ Amori, wipe,
22 Jẹ ki emi là ilẹ rẹ kọja lọ: awa ki yio yà sinu oko, tabi ọgba-àjara; awa ki yio mu ninu omi kanga: ọ̀na opópo ọba li a o gbà, titi awa o fi kọja ipinlẹ rẹ.