23 Nitõtọ kò sí ìfaiya si Jakobu, bẹ̃ni kò sí afọṣẹ si Israeli: nisisiyi li a o ma wi niti Jakobu ati niti Israeli, Ohun ti Ọlọrun ṣe!
24 Kiyesi i, awọn enia na yio dide bi abokiniun, yio si gbé ara rẹ̀ soke bi kiniun: on ki yio dubulẹ titi yio fi jẹ ohun ọdẹ, titi yio si fi mu ninu ẹ̀jẹ ohun pipa.
25 Balaki si wi fun Balaamu pe, Kuku má fi wọn bú, bẹ̃ni ki o máṣe sure fun wọn rára.
26 Ṣugbọn Balaamu dahún, o si wi fun Balaki pe, Emi kò ha ti wi fun ọ pe, Gbogbo eyiti OLUWA ba sọ, on ni emi o ṣe?
27 Balaki si wi fun Balaamu pe, Wá, emi bẹ̀ ọ, emi o mú ọ lọ si ibomiran; bọya yio wù Ọlọrun ki iwọ ki o fi wọn bú fun mi lati ibẹ̀ lọ.
28 Balaki si mú Balaamu wá sori òke Peoru, ti o kọjusi aginjù.
29 Balaamu si wi fun Balaki pe, Mọ pẹpẹ meje fun mi nihin, ki o si pèse akọmalu meje ati àgbo meje fun mi nihin.