1 ISRAELI si joko ni Ṣittimu, awọn enia na si bẹ̀rẹsi iṣe panṣaga pẹlu awọn ọmọbinrin Moabu:
2 Nwọn si pe awọn enia na si ẹbọ oriṣa wọn; awọn enia na si jẹ, nwọn si tẹriba fun oriṣa wọn.
3 Israeli si dà ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ Baali-peoru: ibinu OLUWA si rú si Israeli.
4 OLUWA si sọ fun Mose pe, Mú gbogbo awọn olori awọn enia na, ki o si so wọn rọ̀ si õrùn niwaju OLUWA, ki imuna ibinu OLUWA ki o le yipada kuro lọdọ Israeli.
5 Mose si wi fun awọn onidajọ Israeli pe, Ki olukuluku nyin ki o pa awọn enia rẹ̀ ti o dàpọ mọ́ Baali-peoru.