13 Yio jẹ́ tirẹ̀ ati ti irú-ọmọ rẹ̀ lẹhin rẹ̀, ani majẹmu iṣẹ-alufa titi-aiye; nitoriti o ṣe itara fun Ọlọrun rẹ̀, o si ṣètutu fun awọn ọmọ Israeli.
14 Njẹ orukọ ọkunrin Israeli na ti a pa, ani ti a pa pẹlu obinrin Midiani na, a ma jẹ́ Simri, ọmọ Salu, olori ile kan ninu awọn ọmọ Simeoni.
15 Orukọ obinrin Midiani na ti a pa a si ma jẹ́ Kosbi, ọmọbinrin Suru; ti iṣe olori awọn enia kan, ati ti ile kan ni Midiani.
16 OLUWA si sọ fun Mose pe,
17 Yọ awọn ara Midiani lẹnu, ki o si kọlù wọn.
18 Nitoriti nwọn fi ẹ̀tan wọn yọ nyin lẹnu, eyiti nwọn tàn nyin niti ọ̀ran Peori, ati niti ọ̀ran Kosbi, ọmọ ijoye Midiani kan, arabinrin wọn, ẹniti a pa li ọjọ́ àrun nì niti ọ̀ran Peori.